Ọjọ ti a ba ku, la a dere, eeyan o ṣunwọn laaye.
Ọpọ ninu awọn oṣere tiata papaa jùlọ awọn to jẹ Yoruba lo jade laye laipẹ yii eyi ti o jẹ iyalẹnu fun ọpọlọpọ eeyan.
Ẹkun sọ lagbo awọn oṣere Yoruba lopin ọsẹ to kọja nigba ti iroyin kan jade pe gbajugbaja oṣere tiata ati adẹrinposonu nii Tolani Quadri Oyebamiji ti ọpọ mọ si Sisi Quadri ti dagbere faye.
Yatọ si Sisi Quadri, oun to ṣe ni laanu ni pe awọn gbajumọ oṣere mii, ti aye gba ti wọn, naa ku laarin oṣu mẹfa si oṣu meje sẹyin.
Nitori naa la ṣe ṣe akojọpọ yii lati ran awọn ololufẹ wọn leti nipa wọn.
Sisi Quadri
![Aworan Sisi](https://ichef.bbci.co.uk/ace/ws/640/cpsprodpb/e1fb/live/c7954ad0-da21-11ee-8e51-89964b3d5c0e.jpg)
ORÍṢUN ÀWÒRÁN,IAMSISIQUADRI/INSTAGRAM
Lọjọ Ẹti tii ṣe ọjọ kinni oṣu Kẹta ọdun yii ni iroyin bẹrẹ si tan kaakiri oju opo ayelujara nipa iku rẹ.
BBC Yoruba kan si ọkan lara awọn to kọkọ kede iku rẹ loju opo ayelujara Otunba Adekunle Abolade ti gbogbo aye mọ si Dodo Ede.
Lojuopo rẹ to ti kede iku Sisi Quadri, o sọ pe oun ṣẹ́ṣẹ wo fiimu ti Sisi Quadri ti kopa ninu rẹ Anikulapo tan ni lowurọ oni.
O ni Sisi Quadri ku ninu fiimu naa to siti wa pada jade laye loju aye gangan.
Ninu alaye rẹ to ṣe Dodo Ede ni ilu Ogbomosho ni Sisi Quadri dakẹ si ati pe ni ile iwosan fasiti Ladoke Akintola lo ti n gba itọju lori ailera to n koju lẹnu lọọlọ yi.
Ọkan lara awọn aburo oloogbe Sisi Quadri, Oyebamiji Muktar, ṣalaye fun BBC Yoruba bi iku oloogbe naa ṣe waye.
Okunrin naa sọ pe awọn ti kọkọ gba ipe kan pe o ṣubu nibi to ti n ṣere ori itage lọwọ ki wọn to gbe wale.
O ni “ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keji, ni wọn pe wa pe wọn ṣubu nibi ti wọn ti n ṣere itage lọwọ, aburo wa dẹ lọ gbe wọn nibẹ wale.
“A gbe wọn lọ sile iwosan, wọn si ṣe ayẹwo fun nibẹ, wọn si sọ pe aisan iba ni wọn ni, wọn si ṣetọju wọn nibẹ.
Yatọ si aisan iba ti Sisi Quadri ni, aburo rẹ ọhun tun sọ fun BBC pe o ni arun ọgbẹ inu amọ wọn n tọju rẹ.
Muktar sọ pe oloogbe naa ṣi fi owo ranṣe si awọn lọjọ kejidinlogun, oṣu Keji, ọdun 2024 yii pe ki wọn fi gbẹ kọngadẹrọ ni iranti iya wọn to di oloogbe ni nnkan bii ọdun kan sẹyin.
O fi kun ọrọ rẹ pe oloogbe naa kii sinmi lẹyin ọpọlọpọ iṣẹ amọ awọn mọlẹbi rẹ maa n gbiyanju lati ri daju pe o n sinmi, koda, awọn ti fi akoko igba kan pa foonu rẹ ri ki wọn ma baa pe fun iṣẹ.
Adedeji Aderemi ‘Olofa Ina’
![Aworan Olofa Ina](https://ichef.bbci.co.uk/ace/ws/640/cpsprodpb/a528/live/02512680-da22-11ee-8e51-89964b3d5c0e.jpg)
ORÍṢUN ÀWÒRÁN,OTHER
Gbajumọ eekan osere tiata, Oloye Adedeji Aderẹmi ti ọpọ mọ si Ọlọfa Ina ti jade laye ni aṣalẹ Ọjọbọ, ọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2024.
Ẹni odun metalelaadọrin ni agba oṣere naa ki ọlọjọ to de.
Wọn bi Adedeji Aderemi ni ọjọ kẹẹdogun, oṣu Karun-un, ọdun 1950, ni agboole Jagun-Olukosi niluu Ede, nipinlẹ Osun.
Baba Olofa Ina lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ St. Peters Anglican Primary School.
Lẹyin naa lo lọ si ile ẹkọ girama Baptist Modern Secondary School.
Ṣaaju ko to o di oṣere, o kọ iṣẹ gbẹnagbẹna, ti wọn n pe ni Carpentry ni ede Gẹẹssi lọdun 1965 si 1970.
Bakan naa ni Olofa Ina ṣiṣẹ gẹgẹ bi oṣiṣẹ ijọba ni ileeṣẹ to n ṣe awọn akanṣe iṣẹ ati igbokgbodo ọkọ niluu Ibadan. O sẹ iṣẹ naa laarin ọdun 1970 si 1977.
Iroyin sọ pe ni gbogbo asiko yii ni oloogbe Aderemi ti n ṣe ere ori itage diẹdiẹ. Nigba to di ọdun 1972, o da ẹgbẹ osẹre rẹ, Olofa Ina Theatre Group silẹ pẹlu awọn oṣere mii.
Ẹgbẹ oṣere Olofa Ina ma n ṣe awọn ere ori itage to n sọ nipa itan awọn jagunjagun nilẹ Yoruba.
Wọn ṣe awọn ere to ni i ṣe pẹlu itan Basorun Ogunmola, Balogun Ibikunle, Ogedengbe Agbogungboro, Aarẹ Kunrunmi, Kakanfo ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ori amohunmaworan Nigerian Television (NTV) niluu Ibadan si ni wọn ti ma n ṣe afihan awọn ere naa.
Musiliu Ajikanle
![Aworan Musiliu Ajikanle](https://ichef.bbci.co.uk/ace/ws/640/cpsprodpb/7952/live/037369f0-da23-11ee-8e51-89964b3d5c0e.jpg)
ORÍṢUN ÀWÒRÁN,AGBALA GABRIEL
N ọjọ́ Aje, ọjọ kọkanlelọgbọn, osu Keje, ọdun 2023 ni iku tun ṣọṣẹ ni agboole tiata, pẹlu bi Musiliu Ajikanle, ti ọpọ mọ si Buffalo, ṣe dagbere faye.
Iku Buffalo waye lẹyin ọdun meje to ti n ba aisan rọpa-rọsẹ finra.
Ṣaaju iku rẹ ni ppasitọ kan, Agbala Gabriel, ti n ṣe eto ikowojọ fun oṣere naa, ti wọn si kede pe owo ọhun ti pe miliọnu mẹta Naira.
Amọ, owo naa ko tẹ oloogbe lọwọ to fi ku.
Musiliu Ajikanle gbajumọ fun ipa to ko ninu ere Mufu Oloṣa Oko to ṣe pẹlu Odunlade Adekola.
Murphy Afolabi
![Aworan Murphy Afolabi](https://ichef.bbci.co.uk/ace/ws/640/cpsprodpb/ff7d/live/5f738c70-da24-11ee-8e51-89964b3d5c0e.jpg)
ORÍṢUN ÀWÒRÁN,MURPHY AFOLABI
Gbajugbaja osere tiata, Murphy Afolabi ku ́̀̀lọjọ Aiku, ọjọ kẹrinla, osu Karunun, ọdun 2023, lẹ́ni ọdun mọkandinlaadọta.
Wọn si sin oku rẹ ni ọjọ Aje, ọjọ Kẹẹdogun, oṣu Karun un.
Ile rẹ to wa ni ilu Ikorodu, nipinlẹ Eko, ni wọn sin in si.
Ọjọ karun un, oṣu Karun un, ọdun 1974 ni wọn bi oloogbe ọhun, eyii to mu ko pe ẹni ọdun mọkandinlaadọta ninu ọdun 2023 yii ki ọlọjọ to de
Ilu Osogbo, nipinlẹ Osun ni wọn ti bi oloogbe ọhun
Murphy kawe gba oye Diploma ninu ere ṣiṣe nile ẹkọ gbogboniṣe ipinlẹ Osun to wa niluu Iree lọdun 2001, lẹyin naa lo tun lọ kawe ni fasiti UNILAG, niluu Eko
Ọmọ mẹta ni Muphy Afolabi fi silẹ saye lọ, ọkunrin meji ati obinrin kan; orukọ awọn ọmọ naa ni Afolabi Olamilekan, Afolabi Fathia Moyosore, ati Okikiola Afolabi
Lati kereke jojolo ni Murphy ti bẹrẹ iṣẹ ere ori itage, amọ o bẹrẹ si n fi iṣẹ naa jẹun labẹ agba ọjẹ oṣere ni, Fasasi Olabankewin ti ọpọ mọ si Dagunro, lati ọdun 1998
Irawọ Murphy bẹrẹ si n tan lẹyin to kopa ninu ere ti akọle rẹ n jẹ “Omo rapala”
Ṣaaju iku rẹ, irawọ Murphy tan lagbo oṣere tiata Yoruba ni Naijiria ati loke okun, yatọ si pe o jẹ oṣere, o tun maa n kọ itan.
Ọsẹ kan ṣaaju asiko to jade laye ni Afolabi ṣe ọjọ ibi ọdun kọkandinlaadọta ti ọpọ ẹbi, ara, ọrẹ ati ojulumọ ti baa peju ṣadura.
Mr Ibu
![Aworan Mr Ibu](https://ichef.bbci.co.uk/ace/ws/640/cpsprodpb/92be/live/aa930130-da25-11ee-9cd2-855b583eef0a.jpg)
ORÍṢUN ÀWÒRÁN,MR IBU
Gbajumọ oṣere, John Okafor, ti ọpọ mọ si Mr. Ibu, naa jade laye.
Ọjọ Abamẹta, ọjọ keji, oṣu Kẹta, ọdun 2024, ni Mr. Ibu jade laye.
Ọmọ ipinlẹ Enugu ni.
Mr. Ibu ṣe orisirisi iṣẹ bii onidiri, ayaworan ati awọn iṣẹ pẹpẹẹpẹ mi ṣaaju ko to di oṣere.
Lẹyin to pari nile ẹkọ girama, iroyin sọ pe aisi owo ko jẹ ko lọ si ile ẹkọ giga, botilẹ jẹ pe, o ri anfaani lati wọle.
Ṣugbọn nitori ifẹ to ni si eto ẹkọ, o pada lọ si ile ẹkọ imọ ẹrọ, Institute of Management and Technology (IMT), niluu Enugu, nigba ti owo de ọwọ rẹ.
Ọdun 1998 ni Mr. Ibu bẹrẹ ere ṣíṣe, amọ ogo rẹ ko buyọ titi di ọdun 2004, nigba to kopa ninu ere Mr Ibu.
Ere naa si lo fi gba ami ẹyẹ rẹ akọkọ
O le ni igba fiimu ti Ọgbẹni John Okafor ti kopa nigba aye rẹ.
Lara wọn ni Mr. Ibu, Mr. Ibu 2 , Mr. Ibu and His Son, Coffin Producers, Husband Suppliers, International Players, Mr. Ibu in London, Police Recruit, 9 Wives, Ibu in Prison ati Keziah.
Oloogbe Okafor tun fi igba kan kọrin, to si gbe rẹkọọdu orin to pe ni ‘This girl’ ati ‘Do you know’, jade ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.